Wednesday 16 January 2013

Alfa Oniwaasi



(Alfa Oniwaasi)

E ba mi gb'Olohun tobi (Allah Akbar)
Adupe lowo anobi wa mohammed (S.A.W) ati awon ojise re gbogbo.
A ki gbogbo awon agbaagba alfa ti nbe nikale and awon shehu wa gbogbo. Ki ike ati ola Olohun ma ba gbogbo won.

Pataki oro mi loni ni fun awon odo wa gbogbo.
Eyin janmo, a be ri bi aye se nlo loni ni? Awon òdó wa o osise alalubarika mo loni. A ti wa ni irole aye.
Awon òdó wa o gun okada mo, a f'ise yahoo.
Awon odo wa o sise tailor mo, a f'ise yahoo.
Awon odo wa o sise bricklayer mo, a f'ise yahoo.
Ise oriburuku, ise yahoo yi ise epe ni.

Gbogbo owo oyinbo ni won ti gba tan....won ni owo ti won je awon baba nla awon ni awon ngba pada.
Bi won ba wa je owo yahoo yi tan, won a wa lo ra oko nlanla, awon oko bogini.
Mo ri Kamoru, oloriburuku omo n'ijo jimoh, Mo ni "Kamoru, lati ojo ti o ti ngba control oriburuku to ngba kiri o wa mosalasi mo.....iwo omo musulumi. O tun wa gba owo yi tan o ngun oko ti won pe ni Honda alla. Eyin o ri awon omo kristiani, se won gun oko to nje Honda jesu ri? Se eyin o mo wipe Olohun oba ni nje Allah?!"
Laila illahlahu!

Eyin oloriburuku omo e wa ngun allah gege bi motor. E o le r'orun wo! E gbo mi, awon oyinbo naa ni eleda ti won o. Bi e ba gba gbogbo owo ohun tan ti e se si Naira, walahi to ba je millions tabi Billions- e o ni fi se nkan rere. E o ni fi kobo sile de omo te o fi jade laye lola alquran karim.

Eyin alfa te nba awon omo wonwonyi sise, ti e nba won s'adura, ti e nba di tira, ti e nba won te yanrin ti won nfi sise yahoo- gbogbo yin le o jiya lojo agbende alukiyamo. E o le bo ninu ina allah!

Won pe wa ladugbo kan ka wa bawon se waasi. Lojo naa, ni mo ba se waasi lori oro yahoo yi naa ni. Gbogbo awon omo yahoo adugbo ba pe ara won jo- won na wa daadaa, won ja gbogbo tesibiu wa....won ya gbogbo al-quran. Won ni awon o ni je ka lo a fi bi a ba se adua f'awon.
Nigbati iya yi po eyin janmo, la be bere si se adua fun won wipe: (in a singing voice) " e o ma r'ise, ona o ni di mo yin. Ise yahoo yi yio ma seesee, e o si lalubarika. A toro emi gigun funyin, a toro alaafia. Ki Olohun siju aanu wo yin bo se siju wo ore re mohammed...."

A gbadua yi fun won lojo naa ki won to je ka lo.
Sugbon kini kan da mi loju, gbogbo owo olowo ti e n ji yi, gbese ni yio je funyin. Gbogbo re le o dapada lonakona. E o si j'iya niwaju Olohun. Apaaro ki saaba sori eyin ti kii se ti e- gbogbo nkan oninkan te ji yi le o padanu lase oluhun lola fatia.

Tooo, eyin omo yahoo ti mbe ladugbo yi, s'eyin naa o tun na wa ba ba pari eto loni nitoripe a ba yin wi? Eyin agbagba alfa ati eyin Shehu, se e o ma wo won e je ki won tun na wa loni nitori a ba won so eyi ti nje otito oro?
Se be ri wipe loni emi nikan ni mo nda se waasi. Alfa Jubril, arowaasi mi mbe l'hospital. (in a singing voice) "Awon yahoo ti f'èsé ya gbogbo oju e. Ko le soro, ko le ka ke alquaran mo nigbati won ti f'ese ge ahon e"
Ebe la be yin loni o, e ro ti anobi mo mi lara e je ki nma ba kadara mi lo jeejee.

E je ka t'ewo adura.....



(Transcribed from an audio file shared with me)

3 comments:

  1. Translation please.

    Multi-Called.

    ReplyDelete
    Replies
    1. That will be difficult please. You can help me in that regard.
      Thanks as you do so.

      Delete
  2. Can i get the audio file i had it before

    ReplyDelete