Wednesday 4 January 2017

Waya-waya

(At the courtyard)

Akoda 1: Kini pelebe ti kabiyesi ma n te nigbogbo igba'un, ise ki lo wa fun naa?

Akoda 2: Kini? Se seeti?

Akoda 1: Seeti boo; Se un o wa mo foonu ni? A ni Kini pelebe alapade kan ti Iwo naa ma n gbe tele won...

Akoda 2: oooo, komputa nu'u.

Akoda 1: Dakun Kini won ma n ri te lori re nigbagbogbo naa? Bo de 'yewu, ori re loo ba won. Bi won jade sinu ààfín, oun naa ni won si siwaju ti won nte. Bi won o te, won o sa teju mo koko ni sa!

Akoda 2: Kabiyesi fi n b'awon eebo soro ni.

Akoda 1: Awon eebo were wo? So bere katikati re? A ni won nte nkan, o ni won ba eebo soro....

Akoda 2: O da'kan mo. Awon eebo ni kabiyesi fi n ba soro se. So ri kini'un lo di'po waya-waya aye joun ti a re ma nte n'ile ifiweranse. Eebo ti s'aye dero, inu yara re lo joko si bayi to ti ma te waya ranse ti won o si ma te pada si o.

Akoda 1: Kabiyesi yi sa! Orisirisi nkan ni won sa ko wa lati oke okun.

No comments:

Post a Comment