Wednesday 4 January 2017

Ibasepo ti ko l'anfani

- Igi ta f'ehin ti ti ko gba ni duro, bo ba wo lu'ni ko le pa ni.

- Olowo ta ba rin ti a o yo, aibarin mo o le f'ebi pa ni.

- Oosa bo le gbe mi, se mi bo se ba mi.

.................

Ara ohun ti a le to ka si gege bi irufe okunfa opolopo irinajo to forisanpon ninu odun yi ni ibasepo ti ko ni anfani.

Opolopo ni Ile won to n toro tele daru latari Ore ti won yan.
Opolopo ni owo won to ni aje lori tele di òkùtà latari alabadowopo ti won yan.
Opolopo lo tibi imoran ore ri akoba.
Opolopo lo ni arun eje riru latibi wahala ti awon ebi re nfun.
Opolopo awon eni iyi lo d'eni abuku latari awon ilekun ti won kan lati toro aanu.

B'aye opolopo se ri l'oni nii se pelu iru ibasepo ti won ni pelu awon to yi won ka. Aye to toro, won yan awon alabarin won daadaa ni. Bee naa ni aye to dojuru, bi awon naa se yan ni.

Bi a ba ti wa ri wipe awon ibasepo kan ti a ni nmu iyonu dani, nse lo ye ka wa atunse si. Idi niyi ti mo fi pa awon owe ti mo fi bere oro mi. Aile wa atunse si awon ibasepo ikoro yi lo nmu opolopo pe ninu ogun, tabi ku sinu e.

Ko de soro. Agbara wa lowo olukaluku lati yan ifokanbale fun ara won. Ko s'eni ti a da mo wahala tabi ti a da wahala mo, eda lo n yan wahala tabi gba wahala l'aye lati ba won gbe.

Ko si b'oju ounje ti pon kiniun to n'igbo, ko ni je koriko. Iwo naa ni lati pinu lati ko awon ohun ti o ko ba fe.
Yan awon ore gidi.
Ma so ara re d'eru nitori atije.
Ma fi tipatipa s'owo ti o lere.
Ma se nkan ti okan re o fe nitori nkan ti awon kan yio so.
Fi ifokanbale ati alaafia ara re saaju ohun gbogbo.
Yago fun awon ore gboyi-soyi.
Jina si awon enia k'enimani.
Ma fi oju bale fun awon to je wipe anfani ti won ma je lara re nikan ni won nwa.
Eniti o ba ti dale re leekan ri, ma fun l'aye leekeji.

A ti fun o ni agbara lati yan. Lòó!

AV

No comments:

Post a Comment