Sunday 27 September 2015

Netflix ati chill

IKEDE PATAKI

Iroyin ti fi to wa leti wipe awon omo ìyá meji kan ti n soro kiri ilu bi oká bayi, pelu kiko ibasun fun  gbogbo obinrin ti o ba wo panpe won, ti won a si ri daju wipe o d'oyun.

Oruko awon mejeeji yi ni NETFLIX ati CHILL. Adape won miran a tun ma je NETFLIX AND CHILL.

Awon odaju meji yi ko bowo fun iyawo oba, beeni won ko naani omo ijoye. Won o mo abileko yato si olomoge.
Opolopo ajosepo ololufe ni won ti daru beeni, won ti so awon odomobinrin to sese n balaga sipo oloyun laitojo.

A ro gbogbo eniyan lati kilo fun awon aya won, aburo won l'obinrin ati omobinrin won lati sora fun awon ajanilole-ara mejeeji yi titi owo awon agbofinro yio fi te won.

Eniti ko ba n'ise ko lo wa ise se nitori wipe awon to sa ba ma nko si won lowo ni awon ti owo won dile. Eyi fi daju wipe ooto ni oro ojogbon Albert Eistein (1876) to so wipe 'owo to ba dile ni esu nwa ise fun'.

E ku faaji opin ose!

AV

No comments:

Post a Comment