Sunday 27 September 2015

Iranlowo

OLUWA, JE KI AANU RE GBA IBITI MO WA KOJA

Opolopo wa lo ma n dide lojoojumo lati wa iranlowo lo, tabi lati ke si awon enia lati wa ran wa lowo. Kayefi to wa nibe ni wipe, awon iranlowo ti a ma nri gba je eyiti o tun ma nda wa pada sipo ti a tun ti nilo iranlowo.

Ojoojumo ni Batimeu, afoju, ma nri iranlowo gba lodo awon to ma nse atona re lo si eba ona lati se agbe. Awon to ba nkoja tun je awon alaanu miran to tun ma nran lowo nipa fifun ni toro-kobo ti won ba ni ki o fi jeun.
Bi o ba di owo ojo'ro, awon oluranlowo miran a tun se atona re pada sile.
O nri iranlowo gba lojoojumo sugbon, itan re ko yipada. Gbogbo igba naa lo tun nba ara re pada nipo ti yio ti nilo iranlowo.

Iranlowo ti ko ba yi itan aye eni pada kii se iranlowo.

Okunrin abirun kan wa leti odo Bethesda fun odun mejidinlogoji (38years). Oun naa kuku nri iranlowo gba- o nri awon alaanu ti won nfun lounje, bi bee ko, ko le lo iye odun yi lai jeun-yio ti gbemi mi. Sungbon, iranlowo ti oun naa nri yi ko yi itan re pada. Oun naa si nba ara re lojoojumo ni ipo ti yio tun ti nilo iranlowo.

Eyi ni yio tun mu mi so lekaan si wipe iranlowo ti ko ba yi itan aye eni pada kii se iranlowo.

Lojo kan, awon atona Batimeu, afoju, tun se atona re lo si ipo ti yio tun ti lo wa iranlowo gege bi ise re, sugbon ojo yi yato! Aanu gba odo re koja. JESU KRISTI GBA ODO RE KOJA.

Lojo yi, Batimeu kigbe bi ko ti kigbe fun iranlowo ri. Lojo yi ko bere fun iranlowo, O BERE FUN AANU. O bere fun aanu ti nyi itan aye eni pada. O bere fun ohun kan ti ko ni je ko tun pada sipo ti o ma n ba ara re nigbogbo igba lati wa iranlowo ti ko ba ni kale mo. Lojo yi, o bere fun ohun to je logun ju-  o ni "KI EMI KI O LE RIRAN"

Lehin ti awon to ma n saanu fun okunrin abirun yi fun ni ounje tan lojo yi, oun naa n reti ki ojo na lo bakanna bi o ti ma nri ni opolopo odun. Sugbon, lojo yi, aanu gba odo oun naa koja. Oun o ti e pariwo, aanu kan sawari re laarin ogunlogo enia ni. O ri iranlowo to gaju ounje lo. O ba aanu to nyi itan aye enia pada pade! Oun naa di eni ti o le kuro lojukan lehin opolopo odun ti o ti fi sofo! ITAN RE YI PADA!

Iranlowo ju iranlowo lo!
Eniti a bu omi fun ki o fi re ongbe yato si eniti a gbe kanga fun lati ma bu mu nigbakugba ti o ba fe.

Eyi lo mu mi gba adura yi wipe:

"Oluwa, je ki aanu re gba ibiti mo wa koja!
Awon iranlowo ti mo nri gba lowolowo bayi nda mi pada sipo lati tun wa iranlowo ni. Dakun wa fi iranlowo ti n yi itan aye eni pada ba emi naa pade!"

Bi oro yi ba kan iwo naa lara, o le gba adura yi bakanna.

AV

No comments:

Post a Comment