Saturday 1 October 2016

Ologo -VS- onisowo ogo

Awon kan wa, won ma n ra ogo lowo ologo sugbon won a fi ogo yen sile sowo ologo ko ma s'akoso e.
L'oju gbogbogbò, o ma dabi wipe ologo lo si ni ogo e sugbon otito ibe ni wipe alabojuto  lasan ni nitoripe gbogbo ere ti ogo yen n mu wa,  apo awon onisowo ogo lo n lo, won kan ma ma fun ologo ni diedie ninu e ni.
N to s'eni l'aanu julo ni wipe opolopo igba, o ma n pe ko to ye ologo wipe oun ti di eru ogo oun.

Bawo ni enia se n gbe ogo e ta?
Ki lo ma n fa?
Ki lo ma n mu ki ologo pe ko to niran wipe oun ti d'eru ogo oun?

E r'onu si.

AV

No comments:

Post a Comment