Thursday 5 March 2015

Owo, Ogbon, Alaafia: Ewo le maa mu?

Bi n ba bi yin wipe ninu owo, ogbon, ati alaafia ewo le fe, e o si gbodo mu ju okan lo; e wo le maa mu?

Edumare da elomiran ni olola sugbon ko fun ni laakaye. Bi iru won ba soro tabi hu'wa lawujo, gbogbo enia a si ma w'oye bi o se je pe iru won lo lowo lowo. Aini ogbon lori yi naa ni o je ki won le fi owo ti won ni yi fi se nkan anfani fun ara won tabi awon to yi won ka. Ka lowo laisi ogbon la ti fi gbe ile aye naa ni nda emi opolopo won legbodo.
Ki wa l'afani owo t'ani taa fi se oun rere, to tun wa je wipe asilo owo ohun naa lo ran ni lo si orun osangan?

Bee si ni elomiran je olopolo pipe eda sugbon aje korira re. Ìsé ti ba won mule bi ègbe isu. Osi nba won ji, o n ba won sun ni. Oro won kii ta laarin egbe ati ogba nitoripe oro o dun lenu olosi. Iru awon enia wonyi dabi aro to fe jo ni- Ijo kuku mbe n'nu re sugbon ese ni o si. K'a l'ara ninu ko ma si owo lati fi gbe jade a ma da ironu sinu aye enia. Ironu aroju naa ni nfa awon aisan ti nge emi eni kuru. Iru awon wonyi a ma f'ara sinu ku.
Ki wa l'anfani ogbon t'ani ti ko mu'ni kuro ninu ise ati osi?

Awon kan tun wa wa, aje ti so won di imule beeni ogbon fi odo won se ibugbe sugbon oro won ati alaafia dabi osan ati oru, won kii f'oju kanra won. Iru awon wonyi kii l'emi gigun. Iwonba ojo ti won ba lo l'aye gan ninu inira ni. Won kii lo owo ati ogbon ti won ni d'ojo ogbo. Aye won dabi ododo ipado; to tan yoyo lowuro sugbon ti kii d'ale ko to ro.
Ki wa l'anfani owo ati ogbon t'ani laisi alaafia ati emi gigun lati lo?

Owo, ogbon, ati alaafia mbe lowo yarabi oba oke, a si ma j'ogun e fun awon eda re bo ba ti wuu. Ebe mi si Eledu ni wipe ko ma fi'kankan dun wa mbe. Awon to ni nkan meteeta yi nikan la le so wipe won r'ile aye wa.

AV

No comments:

Post a Comment