Tuesday 24 March 2015

Ojo gbogbo l'odun

Ti awon kan ba ra bata, won a lo ko pamo; won a lo di igba odun ki awon to wo.
Shio! Emi ti o ni d'ola to n da ipari osu.
Ojo t'emi ba ti ra nkan ni mo ma n bere si lo o.

Opolopo lo ni aso daadaa n'ile, sugbon ti won a ma wo aso pipon kiri igboro bi aparo.

Looto, bi a ba ni ki a fi isoro ati wahala ile aye enikookan wa se odiwon bi o se ye ka ma mu'ra, akisa ni o ba to si opolopo wa lati ma wo, sugbon se iyen wa tan nkan to wa nile bi?

Latari eyi eyin ololufemi gbogbo, e maa ranti wipe baa ti rin laa ko ni. E ma rin irin idoti mo. E tun'ra yin se. E mura bi eniti o ni ogo. Eda to ba ti ri imole ojumo tuntun, o ye ko ki ara re ku oriire, o ye ko ri ojo naa bi ojo odun ni.

Se eyin o ri ojo ni, ojoojumo lo nyo togotogo?
Abi e o ri ododo, to nfi ojoojumo yo tewatewa?
Eleda sha da wa niye lori lo ju awon nkan wonyi lo- o da wa ni aworan ara re ni. O ye ka fi ogo yi han. O ye ka fi ewa yi han.

Kii se oge aseju ni mo nso bayi. Beeni mi o s'atenumo eso asedoju anjegbese, mo nso nipa iwontuwonsi imura to ye omoluabi, nitori aseju ohunkohun ko sunwon!

Gbogbo aso olowo iyebiye ti e ko pamo sinu kombodu, ti ikan ati ayan ti fe mu tan yen, e ko won jade ki e wo won! Abi bi e ba ku ta lo fe wulo fun?

AV

No comments:

Post a Comment