Thursday 11 September 2014

A short prayer for the wicked strongholds

Awon to nse bi oba lori aye mi
Awon ti a o gbe ase aye mi le lowo sugbon ti won n pase
Awo to ni niwon igbati awon ba si n mi o ku ibiti ma gbe gba
Emi Mimo ro wo l'oye ki won ye se bi oba mo.
Gba ase ti won nlo lori aye mi kuro lowo won
Niwon igbati won ti pinnu wipe anfani to fun won lati wa laaye, idiwo ni awon yio fi je funmi, Oluwa je ki won fi inira l'ogba
Bi won ba nmi afefe si'mu, ko gbodi lara won
Bi won ba nte ile m'ole, ko gbona mo won
Je ki ibisun won ko di eegun (thorns)
Je ki ile won ko di ahoro
Je ki ireti won l'aye ko pare
Ninu igbe kike ni won ba wa s'aye, je ki won fi igbe inira jade laye
Ninu agbara eje ni won ba wa s'aye, je ki won ba inu agbara eje jade laye
Oorun aye won, je ko wo l'osan gangan.

Ase orun ti a ti fifun mi je ko bo sori adura yi ko de se bee!

Bi o ba wa je wipe emi naa fi ojumo ojo kankan fi gbero bi ti elomiran yio se baje laise lairo, OLUWA DAKUN MA GBO ADURA TI MO GBA YI.


No comments:

Post a Comment