Monday 31 March 2014

At the Palm-wine joint

Ni ile emu:

Drinker 1: Eyin ore, o dabi wipe Olayiwola ni yio wole ninu eto ibo to nbo yi o...a be ri bi okiki re se gba gbogbo ilu kan ni?

Drinker 2: Emi o faramo Olayiwola o. Sebi e mo wipe Omo olowo ni Olayiwola, ko de mo ede ti mekunu nso. Iya le fe fi je ara ilu bi e ba fi omo ola ti ko ji'ya ri s'ipo ase.

Drinker 3: Adisa le mi ti e dibo fun. E sa mo wipe a jo lo sile iwe ni....

Drinker 2: (cuts in) Ewu gidi ni bi e ba dibo fun Adisa!
...Adisa omo oju or'ola ri ti nja'po s'aya... Se lo ma ba ipo ola je.

Drinker 1: Ogbeni, oro re su mi o. Gbogbo won lo n bu enu ate lu. O ni omo olowo o da, won tun mu omo talaka o tun fariga.....ta wa lo to si?

Drinker 2: Ariyo ilufemiloye ni eniti ipo naa to si ti gbogbo ara ilu naa si mo. Bi e ba fi omo olowo s'ipo ase, iya yio je mekunu beeni bi e fi ipo ola to omo talaka le'nu wo yio baraje.

Drinker 3:  Ilu o fe Ariyo o jare! Bi be ko ni, kilode ti ko wole lati igbati o ti ndupo naa?

Drinker 1: Ohun ti emi gbo ni wipe awon enia so wipe o lahun.

Drinker 2: Olooto, olopolo pipe, onirele, ati eniti o ni iberu Olorun ni Ariyo.
Ariyo ko lahun. Awon oloye lo ya onijekuje ati ika. Se e de mo wipe eniti ko ba ti k'owo fun awon oloye ko le ri ona lo.
Ariyo kii gba beeni kii funni ni abetele....eyi ni isoro to ga ju lo ti Ariyo ni.

Drinker 1: Iru eni to niru iwa daadaa bayi la nwa n'ipo ninu ilu sugbon o s'eni laanu wipe iru won ni kii de'be.
Kii la wa le se si oro yi bayi, se ba o se ma wo niyi?
Oro ilu wa yi ma to'ju su ni o.

No comments:

Post a Comment