Wednesday 14 May 2014

Ogun awon àna; ogun buruku ni! (Yoruba Version)

Looto ni oro awon agba to so wipe "Aya (tabi oko) buruku dun fe, (awon) àna buruku ni enia o gbodo ni." Tabi ki n tun so wipe "ile buruku ni enia o gbodo ti lo yan aya tabi oko."

Eyin enia mi, ogun buruku ni ogun awon ana! Eni ba kan lo le so. Awon ile ti enia kii jebi ki o to ko agbako, awon ile ti awon obi tabi egbon eniti a fe ti n fe so ara won di apase. Awon ni won fe so ohun ti e ma je, aso ti e ma wo, owo ti e gbodo ma fun won, ile iwe ti awon omo yin gbodo lo, igbati e gbodo jade, ibiti e gbodo lo, igbati e gbodo sun.
Aimoye ajosepo loko-laya to dun ni awon enia ibi won yi ti da omi ikoro si.

Pelu awon iriri ti mo ti ri ati awon eyi ti mo ti fi eti mi gbo, ojoojumo ni mo ma fi n dupe ore ti Eledua se funmi pelu awon ana oloorire ti o funmi. Be naa ni mo nba aya mi dupe wipe oun naa ri ile rere ya si. Ko ri iyonu bo ti wu ko kere mo.
Mo wa fi ola asiko yi gbadura fun awon ti ko ni ibale okan latari ogun ile oko tabi aya wipe, gbogbo awon aninilara yin ni inira yio de ba. Eniti o ba ni ohun yio ma fooro emi yin, ki Edumare o da guguru wahala sinu agbada fun ki o ma yan. Mo pe olugbeja eniti o lagbara lati dide fun iranlowo yin.
Lati asiko yi lo, e o ni isinmi. Gbogbo igi ti arigisegi won ba tun ti se lati wakati lo, ori ara won ni won o fi ru.

Imoran ranpe ti mo ni fun awon apon ti ko ti laya, ati awon omidan ti won n wa oko ni wipe, e yan re o! E wo ile te fe wo ki e to gbo'ri wole. E ma t'ori ife k'agbako! E se iwadi iru awon apere to mbe ninu ile ti e fe wo. E ma se akiyesi iwa awon ebi yii daadaa bi e ba ti ni oore ofe lati wa pelu won. E ni ifura bi won se n huwa si yin tabi soro si yin. E ma kan ranju sile bi oko olopa lasan, e fi riran!
Pabanbari re patapata ni wipe E GBADUA!!! E be Eledua ki o tan imole si gbogbo ibiti o ba sokunkun.

Bi e ba si aya tabi oko fe, o si sunwon. Bi enia ba si ile ya bi eniti o mu majele ti n pani diedie ni.

Oro mi o ju bayi lo. Ka tun fi ayo pade.

AV

No comments:

Post a Comment