Wednesday 15 January 2014

The explosion at work

Mo ranti ojo ti mo gbe obe ayamase lo si ile ise mi tele. Mo fe fi gbesan lara awon omo to ma nje curry yen ni.

Losan, nigbati oju gbogbo pe, mo gbe obe naa sinu ero amounje-gbona (microwave), mo ko'na mo fun iseju marun, emi pada si ijoko mi loke.

Nibi iseju melo kan, oorun gba gbogbo ile ise, mo gbo ti gbogbo won nwuko, ti won nsin; mo so lokan mi pe 'e o ti mo nkankan'.
Ko pe lehin e ni eran saki to mbe ninu obe yi be gbamu! Beeni okan lara awon osise sare wa pe mi wipe 'your food has exploded'. Erin arin-lamiloju ni mo rin lojo naa.

Nigbati emi gan wa nje, ni se ni oogun nbo lara mi bi alagbase to nl'agi ninu oorun.

No comments:

Post a Comment