Friday 12 June 2015

O ye Olorun. Iwo ni ko ye.

O ye Olorun ti ko fi je ki iranlowo o t'owo awon kan to f'okan si yen san d'odo re.

O mo ohun to nse ti ko fi f'eto igbega re s'ikawo awon to ro yen.

Ko kuku se asise nigbati ko fi je ki ajosepe iwo ati awon kan ko se deedee mo.

Iwo ni gbogbo nkan ru l'oju. Ohun gbogbo lo ye Olorun.
Ohun nikan lo n gbo gbogbo kelekele ero okan eda patapata.

Gbogbo igba t'o n j'apa mo'nu, to n binu yen, ailoye ola lo nse e. Aimokanmokan lasan lo n da e laamu. Oni lasan lori, ola sokunkun si o.

Nje o mo wipe awon alaanu kan wa to je wipe amunisin niwon. Eyin lasan lo bere ti won fun e, sugbon odidi akuko adie ni won o fi gba pada lowo re?

Nje o mo wipe awon oluranlowo kan wa to je wipe awon naa ni won ma s'eto bo se ma jabo bi won ba gbe o d'oke tan sugbon ti o ko lati se ife won?

Nje o mo wipe awon oore kan wa, idaduro ni won o ba je fun o l'ola ka lo ti ri won gba ni?

Nje o mo wipe awon alabadowopo kan wa to je wipe amunipadanu gbogbo ikojo enia niwon?

Nje o mo wipe awon abanirinrinajo kan wa to je wipe adanilonaru enia ni won je?

Olorun wa n gba oromodie re lowo iku, iwo ni ko fe ko lo akitan lo je.
Bi a ba si o l'oju inu ni, o ri wipe okere lo ye ko ti ma wo awon kan, won kii se eniti o ye ko wa iranwo de odo won.

Je ki ipinu Olorun fun aye re wa si imuse bo se s'eto re, ma ran Olorun lowo.

Fi igbagbo re s'inu Olorun kii se ninu enia.
Enia naa ni Olorun yio ran si o lati se o laanu, sugbon ohun nikan lo mo awon enia tire ti yio lo fun o. Yio si sele l'asiko to ti pin'nu re ni lai mu inira dani.

Olorun eto ni. Iwo ni ki o ni igbagbo ninu Re wipe o mo ohun t'o nse, ki o si gba l'aye ninu aye re lati sise.

AV

No comments:

Post a Comment